FARADA ÌPÈNIJÀ KÓRÈ PÈLÁYÒ

Endure challenges reap joyfully
(English version on the way.)

FARADA ÌPÈNIJÀ KÓRÈ PÈLÁYÒ

Orin Dáfídì orí 126 ẹsẹ 5
Àwọn tí ń fì omijé fún irúgbìn yíò fi ayọ̀ ka.

Àgbè

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó kúrò nínú oko ẹrú

Wọ́n padà sí ilé ṣùgbọ́n wón wá ninu àìní

Wọ́n ní láti fúnrúgbìn nínú àìní àwáwí àti omijé.

Krìsìtẹ́nì

Krìsìtẹ́nì tí kúrò lábé ìgbèkùn Sátánì Èṣù ese ayé àti ẹran ara

Krìsìtẹ́nì sì wà nínú ayé pẹ̀lú awawi nínú àìní àti omijé.

Gégé bíi àwọn àgbè yóò ti fi ayọ̀ kó irè oko wọn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa
Krìsìtẹ́nì yóò fi ayọ̀ gba ìbùkún wa nínú ìjọba Ọlọ́run tí a bá sìṣẹ́ dára dara.

Àgbè
Àgbè á ṣe làálàá nínú oko
Wọ́n á sán oko
Wọ́n á gbìn èso
A óò dá ààbò bo irúgbìn
Gbígbàdúrà fún òjò tí òjò ìgbà ìrúwé kò bá rò déédéé
Wọ́n ṣe Ìkórè èso ní àkókò tí ó yẹ
Pípa ìkórè mó
Ṣíṣe ìtọ́jú àwọn èso tí wọn yóò tún gbin

Krìsìtẹ́nì
A ó ṣe ìpolongo
Krìsìtẹ́nì a ṣe ìbẹ̀wò àwon tó di ẹni ìgbàlà
Wọn a dáàbò bo àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ẹni ìgbàlà lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké
Wọn a mú wọn dàgbà sókè nípa ti èmi
A ó kó wọn bí wọn yóò se sọ èso
A ó máa gbàdúrà fún won

Ìfaradà àgbè àti ti Krìsìtẹ́nì

Wọn yóò fúnrúgbìn
Nínú ojo
Pẹ̀lú ìpinnu
Àfojúsùn
Nínú ebi
Nínú òùngbẹ
Pẹ̀lú sùúrù
Nípa ìjóloòótó
Àti ìfaradà

Àwọn Krìsìtẹ́nì ìgbà ani là orisirisi kọjá nítorí ìhìn rere wón se àṣeyọrí àwa náà yóò ṣe àṣeyọrí ní orúkọ Jésù àmín

Kọ́ríńtì kejì 11 Ẹsẹ 22 sì 2 7

Hébérù ni nwọ́n bí ? bẹ̃li èmi . Israeli ni nwọ́n bi? bẹ̃li emi. Irú ọmọ Ábúráhámù ni nwọ́n bí ? bẹ̃li èmi .

Ìránṣẹ́ Kristi ni nwọ́n bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọ́n yọ; niti lãlã lọ́pọ̀lọpọ̀ , ní ti pàṣán mo ré kọjá , ní ti túbú nígbà ku gbà , ní ti ikú nígbà púpò .

Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín kan lọ́wọ́ àwọn Júù .

Nígbà mẹ́ta li a fi ògo lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li òkúta, ìgbà mẹ̀ta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati òru kan ni mo wà ninu ibú.

Ni ìrin àjò nígbàkúùgbà , nínú ewu omi, nínú ewu àwọn olọ́sà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn Kèfèrí, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu li aginjù, nínú ewu lójú òkun , nínú ewu láàrin àwọn eke arákùnrin ;

Nínú lãlã àti ìrora , nínú ìṣúra nígbàkúùgbà , nínú ebi àti òùngbẹ, nínú ààwẹ́ nígbàkúùgbà , nínú òtútù àti ìhòòhò.

Lẹ́hìn gbogbo rè ayò púpò ni yóò kéyín rè.

Àpeere ni a rí nínú ìgbésí ayé Paui Àpọ́sítélì tí ó yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun

2Tímótì ú orí 4 ẹsẹ 8

Láti isisiyi lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa , oní ìdájọ́ òdodo , yóò fi fún mi li ọjọ́ náà , kì iṣe kìki èmi nìkan , ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn an rẹ̀.

Àgbékalè Ọlọ́run lórí gbigbin
àti kíkà

A gbọ́dọ̀ gbìn kí á tó le è ká
Ohun tí a bá á gbìn la máa ká
Ìkórè máa ń pò ju ti ìfúnrúgbìn

Gbigbin àti ìkórè gba sùúrù

Fífi àkókò ṣòfò mú ìbànújé wá

Gbigbin jẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́

Sátánì Èṣù máa ń ṣe lòdì sí ìfúnrúgbì

Ìhìn Rere Mátíù 13 ẹsẹ 25

Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ.

Ijèrè ọkàn

Krìsìtẹ́nì́ ní làti lè lọ àwọn agbekale wọ̀nyí fún ijere ọkàn

Lẹhin ohun gbogbo ayò yóò wà. Ayọ̀ àṣeyọrí,

Ayọ̀ ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run

Ayọ̀ isodi púpò

Nehemáyà 12 ese 43 tí

Li ọjọ́ náà pẹ̀lú n wón ṣe ìrúbọ ńlá , nwón sì yọ̀ nítorí Ọlọ́run ti mú wọn yọ̀ ayọ̀ ńlá, aya wọn àti àwọn ọmọdé yọ̀ pẹ̀lú , tó bẹ́ẹ̀ tí a sì gbọ́ ayọ̀ Jerúsálẹ́mù lí òkèèrè réré.

Lúùkù 10 ẹsẹ 17

Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wípé, Olúwa , àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa lí orúkọ rẹ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni a ó yọ̀ nínú ìjọba Ọlọ́run tí a bá forí tíì nínú ayé yìí. Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́ àmín.

%d bloggers like this: